O ní plugin tuntun tó dára, o sì n retí láti fún un ní ìfarahàn. O wà ní ibi tó tọ́. Kàn béèrè lọ́wọ́ wa láti gbà á ní àlejò fún ọ. O ó lè:
- Máa tọpinpin iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ti ṣe ìgbàsílẹ̀ rẹ̀.
- Jẹ́ kí àwọn ènìyàn fi àwọn àbá sílẹ̀ nípa plugin rẹ.
- Gba ìbò fún plugin rẹ ní ìfiwéra pẹ̀lú gbogbo àwọn plugin WordPress tó dára mìíràn.
- Fún plugin rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfarahàn nínú ibi ìpamọ́ àárín yìí.
Àwọn ìdíwọ́ kan wà
- Your plugin must be compatible with the GNU General Public License v2, or any later version. The plugin should either include its human-readable source code or provide a clear, accessible link to it. We strongly recommend using the same license as WordPress — “GPLv2 or later.”
- The plugin must not impose artificial restrictions on its built-in functionality. This includes license gates, paywalls, time-limited trials, usage quotas, or any other mechanism that limits features included in the plugin code and/or that the plugin code can do.
- Plugin kò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun tí kò bófin mu tàbí tí ó burú níwà (èyí jẹ́ ti ara ẹni, a mọ̀).
- O ní láti lo ibi ìpamọ́ Subversion tí a fún ọ kí plugin rẹ tó lè hàn lórí ojúlé yìí. Ìwé Àkójọ Plugin WordPress jẹ́ ojúlé ìgbàlejò, kì í ṣe ojúlé àtòjọ.
- Plugin kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ìjápọ̀ ìta sí ojúlé gbogbogbòò (bíi ìjápọ̀ “agbára láti ọwọ́”) láìgbà àṣẹ olùṣamúlò ní pàtó.
- Plugin rẹ gbọ́dọ̀ tẹ̀lé àkójọpọ̀ àwọn ìlànà kíkún wa, èyí tó kan àìjẹ́ olùfiránṣẹ́ àìfẹ́ àti àìṣe ìlòkulò àwọn ètò.
Ìgbéwọlẹ̀ rọrùn
- Forúkọsílẹ̀ fún àkópamọ́ lórí WordPress.org.
- Fi plugin rẹ sílẹ̀ fún àgbéyẹ̀wò.
- Lẹ́yìn tí a bá ti ṣe àgbéyẹ̀wò plugin rẹ pẹ̀lú ọwọ́, a ó fọwọ́sí i tàbí kí a fi lẹ́tà sọ̀nrọ̀sọ̀ ránṣẹ́ sí ọ láti béèrè fún ìwífún síwájú sí i àti/tàbí láti ṣe àwọn àtúnṣe.
- Lẹ́yìn tí a bá ti fọwọ́sí i, a ó fún ọ ní àṣẹ sí Ibi Ìpamọ́ Subversion níbi tí o ó ti pa plugin rẹ mọ́.
- Láìpẹ́ lẹ́yìn tí o bá ti gbé plugin rẹ (àti fáìlì readme!) sí ibi ìpamọ́ yẹn, a ó fi hàn ládàáṣiṣẹ́ nínú olùṣàwárí àwọn plugin.
- Ṣàyẹ̀wò FAQ fún ìwífún síwájú sí i.
Àwọn fáìlì Readme
Láti jẹ́ kí ìwọlé rẹ nínú olùṣàwárí plugin wúlò jùlọ, plugin kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ní fáìlì readme tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ readme.txt tó bá ìlànà fáìlì readme plugin WordPress mu. O lè fi fáìlì readme rẹ sí inú olùṣàyẹ̀wò readme láti ṣàyẹ̀wò rẹ̀.